Ní ìgbà kan rí, ẹyẹ abàmì kan wà nílùú kan tó máa ń da àwọn aráàlú láàmú nípa kíkó wọn ni oúnjẹ àti pípa àwọn ọmọ wọn jẹ. Gbogbo ọgbọ́n ni wọ́n ti dá tí wọ́n kọ́ lè mú ẹyẹ yìí. Ní ọjọ́ kan Ìjàpá bọ̀ síta, ó sì sọ pé òun yóò mú ẹyẹ abàmì yìí tàbí kí òun pa á. Gbogbo àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ni fi Ìjàpá ṣe yẹ̀yẹ́ ṣùgbọ́n kò kọbiara sí wọn. Ó pinnu láti pa itú ọwọ́ rẹ̀.
Ìjàpá lọ wá odó irin, ó sì ní kí wọ́n da odò yìí bo òun mọ́lẹ̀. Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́ òru, ẹyẹ yìí fò dé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí máa kọ orin bí iṣẹ́ rẹ̀.
Lílé: Èmi ẹyẹ, èmi ẹyẹ tí ì pẹyẹ jẹ ti dé
Èmi ẹyẹ gàngànrúkù sojú ọ̀run gàngànganganrúkugankúò
Ègbè: Ẹyẹ gàngànrúkù gànkú o ẹyẹ
Bí ẹyẹ yìí ṣe kọ orin báyìí ni Ìjàpá náà dáa lóhùn báyìí:
Lílé: Èmi ahun, èmi ahun tíì pẹyẹ jẹ dé
Èmi ahun gàngànrúkù sojú ọ̀run gàngànganganrúkugankúò
Ègbè: Ahun gàngànrúkù gànkú o ahun.
Bí ẹyẹ abàmì yìí ṣe gbọ́ ohùn lábẹ́ odó ni ẹyẹ yìí bá fò lé orí odò irin tí Ìjàpá dà bo orí. Ẹyẹ yìí fi igogo ẹnu rẹ̀ ṣá odó irin, ṣùgbọ́n ṣe ni ẹnu rẹ̀ ẹ́ tẹ̀. Bí ó ti ṣe eléyìí ni Ìjàpá tún bẹ̀rẹ̀ orin bí ti àkọ́kọ́. Ẹyẹ yìí tún bínú pé ẹnìkan lè lórí láyà láti dá òun lóhùn.
Ó tún fi ẹnu rẹ̀ tí ó ti tẹ̀ yìí ṣá odó irin, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣe títí ẹnu rẹ̀ dá tí òun náà sì kú.
Ìjàpá bọ́ sóde ó rí ẹyẹ náà tí ó ti kú ni ó sì gbé òkú rẹ̀ lọ sí ilé Ọba.
Báyìí ni Ìjàpá ṣe fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀ ṣẹ́gun ẹyẹ tí ó ti ń da gbogbo ìlú láàmú fún ìgbà pípẹ́.
Ìtọ́kasí: Àkójọpọ̀ Àlọ́ Àpagbè
Leave a Reply